VIDEO: Awon Olokada Soka Fesun Fifiayeninilara kan Sunday Igboho

Ni deede Agogo Merin osan Ojoru Wednesday ni Awon Olokada Soka wa si ofisi Oyo state park management eyi ti o wa ni podo lati fi erunu han Lori bi Sunday igboho se n fi aiye ni won Lara.
Ninu oro ti won so,won je ki o di mimo wipe leyin ti Awon ti je ki gbogbo aiye mo losetokoja wipe Sunday Igboho ma n lo OMOOLE eyi ti o je alaga olokada Soka tele lati maa gba Owo ipa lowo awon ti o si tun man jegaba Lori awon ni awon ti ko sinu hilahilo.

Agbenuso won je ki o di mimo wipe opo ninu  awon ni awon toogi Sunday igboho ti lu ni alubamiojo,ti opolopo  ninu awon si ti juba ehoro.

Won wa n ra Owo ebe si ijoba ipinle Oyo pe ki won dakundabo  gba awon lowo alagbara ti o n fi Owo ola gba awon loju

Ikan Lara won je ki o di mimo wipe iro patapata ni oro ti Igboho so wipe oun kii gbowo lowo won gege bi won ti se fesun kan
Won wa pee nija wipe ki o jade sita lati bura  wipe oun kii gbowo

Won wi siwaju wipe ki ijoba ran awon otelemuye lati lo si Soka lati lo se iwadi lori bi awon OMO isota Sunday Igboho se ma n wu iwa jagidijagan.

Won fi ikan se apeere bi ikan Lara awon OMO re ti inagije re nje SAIPON eyi ti o je Alaga maruwa tele se lu manager Truck master ati iyawo re  ni alubamiojo ni ojo die seyin, leyi ti awon OLOPA  SANYO ko si ri nkankan se sii.

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.

Discover more from MouthpieceNGR

Subscribe now to keep reading and get access to the full archive.

Continue reading